Log in | Create account

Translations 

Yoruba 

E káàbo si Ijoba Ìbílè ti Barking ati Dagenham

Ijoba ibile Barking ati Dagenham ma n pèsè awon ètò oniruuru bi ètò èkó, ètò ile gbígbé, ètò ìbójútó àyíká, ètò fun Àgbàlagbà ati Agbègbè ti won n gbè, ètò bi a se n kó awon ilé ijoba pèlu awon anfàní ti ètò ile gbígbé. Ijoba ìbíle wa ma n sisé pelu awon ilé ise ti ibile ati ti gbogbo gbò lati kapa awon iwa ti o l'òdì si òfin, aini, aifinipeni, pelu aika awon eniyan miran kun.


Bi e se le kan si Ijoba Ibile yi: 

Lori èro ayarabiàsá

Ti e ba fe san owo fun Ijoba Ibile, ona ti o yara ju lo ni ki e lo si ori ero ayarabi asa nipa yiyan Pay it.

Ti e ba fé mo ibi ti awon ètò ohun amuludun ti ijoba pèsè fun agbègbè gege bi ile ìwòsàn, ilé èkó alakobèrè ati beebe lo, yan Find it lori èro ayarabiasa.


L'ori èro ìbánisòrò 

E lè pe ile ise wa ni ori èro ibanisoro nomba 020 8215 3000 [ojo Ajé si ojó Etí, lati agogo mejo òwuro si agogo mejo alé].

Ti e ba fe ri wa ni ojúkojú 

Fun awon ti o ba fe ri awon osise wa l'oju koju, e lè wa si awon ile ise wa ni:

Barking
One Stop Shop
2 Town Square
Barking
IG11 7NB
Èro ibanisoro: 020 8215 3000

Awon igba ti a n si: ojó Ajé, Isegun, Ojóbò ati ojo Eti: aago mesan owuro si meje alè.

Ojórú ati Abameta: aago mesan owuro si marun iròlé.

Dagenham
One Stop Shop
1 Church Elm Lane
Dagenham
RM10 9QS
Èro ibanisoro: 020 8227 2970

Awon igba ti a n si: ojo Aje titi di ojo Eti: aago mejo àbò owuro si marun irole.


E beere iranlowo l'owo òré 

A ri wipe ètó wa ni lati pèsè olùtúrò fun awon ti ko ba gbo ede gèési. Sugbon, a gba yin ni imoran wipe ki e wa ore tabi ojulumo ti o le so tabi ti o le ka ede gèési lati ran yin l'owo ti e ba fe kan si wa lakoko. Eyi yio ran awa ati eyin l'owo lati pese ohun ti e fe ni akoko.

A le yi oro pada si ede abinibi yin 

A le pese opolopo awon iwe ijoba ni ede oniruuru ti e ba beere fun. A le pese eda oro ti a ko ni nnla tabi ki a pese oro ni ona asoromagbesi fun awon ti ko riran daradara.

Ti e ba fe alaaye si, e pe eka ijoba ti o n da si oro Ori o j'ori ni adirésì ti a fi han nibi yi,


Eko kikó ni ede gèési 

Tí ede gèési o ba ki n se èdè abinibi yin, ti e si fe mo ede nã daradara si, ile eko giga ti awon agba [Adult College] pelu Ile Eko Giga ti Barking n pese eko kiko ti o ba je wipe:

E je eni ti o n gbe ninu Europe [EU]; 

ti e ba ni ise lowo / ti e ko gba owo kankan l'owo ijoba, e o san gbogbo owo eko yin.

ti e ba n gba owo ijoba kankan, owo idanwo nikan ni e o san.


Ti e o ba ki n gbe ni Europe; 

odun melo le ti n gbe ninu ilu yi
se e ni iwe igbelu
Ilu ti e ti wa.

Ti e ba fe ifilo l'ekunréré, e lo si ile eko giga ti awon agba [Adult College] pelu Ile Eko Giga ti Barking. E jowo mu iwe idanimo yin dani, gégé bi iwe irinna, ohun ti yio fi adiresi yin han ati iwe owo ijoba kankan ti e ba n gba. Won le ni ki e san poun mewa [ti a kò ni da pada] lati be bi e se gbo ede gèési to wo; ibewo yi le gba odiidi ojo kan lati je ki a mo bi e se nilo eko ede gèési si. Nitori eyi, e ni lati beere l'odo awon ile eko giga wonyi ki e to wa.

Ile Eko giga ti Barking [Barking and Dagenham College]
Dagenham Road
Romford
Essex
United Kingdom
RM7 0XU

Ile eko giga ti awon agba [Adult College]
Fanshawe Crescent
Dagenham
RM9 5QA

Equalities and Diversity Team

Town Hall

1 Town Square

Barking

IG11 7LU

 

Phone: 020 8227 2105

Email: 3000direct@lbbd.gov.uk